OMINIRA (Freedom
*OMINIRA*
Olorun da eniyan lati wa ni ominira. Eniti o ba wa ni ominira kosi labe isakoso tabi idari enikeni pelu ipa tabi agbara. Eniti o ba ni ominira leto lati se ohun to ba wu. Eni ti o ba ni ominira, kii se eru fun enikeni. Idakeji ominira ni igbekun tabi ki eniyan je eru.
Eniyan feran ominira. Ero eniyan nipa ominira ni pe ti oun ko ba ti wa ninu ogba ewon tabi ti won ko te eto oun loju, oun wa ni ominira. Bibeli ni Iwe Romu 6:16 so wipe *"Enyin ko mo pe, eniti eyin ba jowo ara nyin lowo fun bi eru lati maa gbo tire, eru eniti eyin ba gbo tire li eyin ise; ibaase ti ese sinu iku, tabi ti igboran si ododo."*
Jesu Kristi fi idi oro yi mule ninu Iwe Johanu 8:34 wipe *"Looto looto ni Mo wi fun yin, Enikeni ti o ba ndese oun li eru ese"*. Gege bi a ti ka ni Romu 6:16 pe eniti o ba jowo ara re fun ni iwo yio je eru fun. Opolopo eniyan lo je eru fun ese ati esu ti won sin nro wipe won wa ni ominira, laimo wipe inu igbekun esu ni won wa.
Awon wonyi je eru fun ese bi - Agbere, Pansaga, Siga mimu, Otin mimu, Wobia, Iwa-eeri, Irira, Ipaniyan, Irede-Oru, Ija, Ibinu, Ogun oloro lilo, Ifowo-bara-enisere (Masturbation), Gbigba abetele, Eso sise (Fashion), Owo, Orisa bibo, Iro, Isoro eniyan lehin, Itanje, Aje, Oso, Emere, Ole, Ojukokoro, Igberaga, Ibalopo to lodi, Iwa bururu ati Iwa Ika gbogbo. (Ka Iwe Romu 1:28-32, Galatia 5:19-21, Ifihan 21:8 fun imo ati alaye si lori ese.)
Niwon igbati o ba ti jowo ara re bi eru fun ikankan ninu awon ese wonyi, o ti di eru fun ese ati esu.
O le je olowo tabi eniyan pataki lawujo, o si le je eniti awon eniyan mo gegebi *"iranse Olorun,"* niwon igbati o ba ti nda ikankan ninu awon ese wonyi, o ti di eru fun ese ati esu. O ti wa ninu igbekun satani. O ko ni ominira nitori pe satani lo nse akoso aye re.
Jesu Kristi so fun awon eniyan kan ti won ro wipe won ni ominira sugbon ti won ndese ni Iwe Johanu 8:44 wipe *"Ti esu baba nyin ni eyin ise, ifekufe baba nyin ni e si nfe se. Apaniyan ni oun ise lati atetekose, ko si duro ninu otito; nitori ti ko si otito ninu re. Nigbati o ba nseke, ninu ohun tire ni o nso, nitori eke ni, ati baba eke."* Nitorina, o le je eru ese ati esu ti o je ona si iku ati orun apaadi, tabi ki o je eru ododo ati Olorun ti o je ona si otito ati iye ayeraye ni orun rere. Bibeli ni Iwe Romu 6:13 so wipe *"Beeni ki eyin ki o mase jowo awon eya ara yin lowo fun ese bi ohun elo aisododo; sugbon e jowo ara nyin lowo fun Olorun, bi alaaye kuro ninu oku, ati awon eya ara nyin bi ohun elo ododo fun Olorun."*
*BI OSE LE DI OMINIRA ATI OLODODO*
O le di eru ododo tabi olododo nipa otito ti o ba mo. Jesu Kristi so ninu Iwe Johanu 8:32 wipe *"E o si mo otito, otito yio so nyin di ominira"* Jesu Kristi ni Otito, Oun si ni ona lati bo ninu igbekun ese ati esu. Ihinrere Jesu Kristi ni agbara Olorun si igbala fun enikeni o ba gbaagbo.(Romu 1:16).
Ti o ba fe bo lowo igbekun esu ati ese, o gbodo gba Jesu Kristi gege bi Oluwa ati Olugbala re, ki o si gbagbo ninu ise irapada eniyan ti o se lori igi agbelebu. Johanu 8:36 wipe *"Nitori naa bi Omo ba so nyin di ominira, e o di ominira nitooto."*
Ona kansoso si ominira tooto laye ati ni ayeraye ni Jesu Kristi. O ko le je eru fun ese ati esu laye, ki o si ro wipe iwo yio ni iye ayeraye lodo Olorun nigba ti o ba ku. Jije eru fun ese ati esu ni ona si iparun ayeraye. Oro Olorun ni Johanu 3:16 wipe *"Nitori Olorun fe araye tobee ge, ti o fi Omo bibi Re kan soso funni, ki enikeni ti o ba gba a gbo ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun."* Iye ainipekun ti bere ti o ba ti gba Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala re. Ti o ba setan lati ko ese ati esu sile ni gbogbo ojo aye re, ki o si je ti Jesu Kristi patapata, wa ni iye ainipekun. Jesu Kristi ni agbara lati gba o kuro ninu igbekun ese ati esu. Ko si bi ese re ti buru to tabi po to, Jesu Kristi yio gba o, ti o ba setan lati fi aye re fun. Gbogbo agbara laye ati lorun je ti Jesu Kristi. (Matiu 28:18). Ti o ba fi aye re fun Jesu Kristi, ti o si setan lati tele oro Re ti nse Otito ti yio so o di ominira, wa bo lowo ese ati igbekun esu.
Mase je ki esu o deru ba o pe o ko le bo, iro lo npa, ko si ohun ti o soro o se fun Olorun. (Luku 1:37).
Olorun feran re nitori eda Owo Re ati aworan Re ni o. Olorun fe ki o jowo aye re fun Jesu Kristi nigba ti o wa laye, ki o ma ba wonu iparun ayeraye lehin iku nitori ese. Nitorina fi aye re fun Jesu Kristi ki o si di omo Olorun. O ni eto lati yan lati kuro ninu ese ki o di ti Jesu Kristi tabi ki o ma tele esu ki o si ma je eru ese, sugbon ranti pe inu iparun ayeraye ni wa pari irinajo aye re si pelu esu.
Ti o ba fe di ominira ni tooto, ki o si tun ni iye ainipekun pelu Jesu Kristi, o gbodo gbe awon igbese wonyi -
*(1)* - O gbodo gba wipe elese ni o. O gbodo ri ese re bi Olorun se ri ese. O gbodo mo wipe ese je ise lodi si ofin Olorun. O gbodo ri ese bi ise ati iwa ti ko dara.
*(2)* - Ironupiwada - Ti o ba ti ri ese bi iwa ti o lodi si ofin Olorun, o gbodo ni ikaanu fun ese re. Eniti o ba ronupiwada nitooto gbodo ni ibanuje ninu okan re nitori ese re, ki Olorun si ri okan re pe lotito o ti ronupiwada.
*(3)* -Ijewo Ese - Ti o ba ti ri awon nkan ti o nse ti ko dara bi ese, ti o si ti ronupiwada, o gbodo jewo gbogbo ese re fun Olorun. Ko gbogbo ese ti o ranti sinu iwe, ki o lo siwaju Olorun ninu adura pelu irele lati jewo ese re nikookan. So fun Emi Mimo ki o ran o leti awon ese ti o ti gbagbe ki o ba le jewo won. Bere fun aanu ati idariji ese re. Ki o si tun bere wipe ki Eje Jesu Kristi o we o mo, ki o si pa gbogbo ese re re. Ti o ba bo ese re mole, ti o ko jewo gbogbo re, o ki yi o ri aanu gba.(Iwe Owe 28:13)
*(4)* - Pe Jesu Kristi sinu okan re - Ka Iwe Romu 10:9-10, ki o si tele e lati fi enu ara re jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala re, ki o si gbagbo ninu okan re pe Olorun ji i dide kuro ninu oku.
*(5)* - Ko gbogbo ese re sile - Ti o ba ti ronupiwada nitooto, o gbodo ko gbogbo ese re sile, ki o si ni ipinu wipe o ko ni pada sinu ese mo. Ti o ba fe ba Olorun rin, o gbodo ko gbogbo ese re sile. Ti o ko ba ko ese sile, o o wa ninu igbekun satani, wa si ma je eru ese. O gbodo ko gbogbo ese sile ko ba le di ominira nitooto. Gbadura, ki o bere fun oore ofe lati le bori gbogbo ese.
*(6)* - Igbagbo - O gbodo ni igbagbo ninu Olorun pe O ti dari ese re ji o, ati pe O si ti gba okan re la. Ti o ba fe ba Olorun rin o gbodo simi le e, ki o si gba a gbo patapata. (Heberu 11:6)
*(7)* -Darapo mo ijo Jesu Kristi ti won ti nwasu otito oro Olorun. Ijo ti ko gba ese laye. Ti won nwasu iwa mimo ninu ati nita ti o le mu o de ijoba orun.
*(8)* - Ma gbadura, ki o si ma ka Bibeli lojojumo, nitori bi o ba se ni imo otito, ti nse oro Olorun si, ni wa di ominira si.
Pinu loni pe o ko ni padanu iye ayeraye ti Jesu Kristi nikan je ona si. Ki Oluwa ki o ran o lowo. Amin.
Fun Ibere tabi ti o ba fe iwe ihinrere yi sii, kan si
*Free Tracts and Messages. Akure. Ondo State. Nigeria.*
08034993038, 08151273110.
Tabi
ebemt.blogspot.com
ezraminds@gmail.com
08119996171
Comments
Post a Comment